Mama's Eulogy (ORÍKÌ)
Created by Babatunde 3 years ago
ORÍKÌ MÀMÁ ADEBỌ̀WALE ỌMỌ ODUṢINA
Ọmọ Ọ̀jọ́wọ̀, ọmọ olókinnẹ,
Ọmọ abẹ́rẹ́ ò wàkọ̀
Ó wàkọ̀ tán ó ṣenú àkọ̀ lòjolòjo.
Ọmọ Jíbówú Òdoṣẹ̀nbádéjọ
A bi ṣòkòtò yẹm̄bẹrì, yẹm̄bẹrì
Ó m bẹ nílé, ó ḿ bẹ lóko
Ọmọ olóko Àgáàrà,
Ọmọ aròko-ròmi, oní pòpòǹdó, àjáijátán
Abigi owóó so lóko bi ẹwẹlẹ
Ọmọ Ó-núgbó-títí,
Ó bá Òdo Aaisọ́nyìn àti Òdo Àámúṣẹ̀ngún pààlà,
Ọmọ olóbì wọ̀rọ̀kọ̀ ẹ̀bá ọ̀nà
Èé ṣààánú ẹni, áá wọ̀ sẹ́rù ẹni,
Èyí tí kò ṣààánú, áá wọ̀ sẹ́yìn oko,
Ẹranko igbó áá fi jẹ.
Omo ọ̀pẹ̀rẹ̀kẹ́tẹ̀ rí dàgbà, inú asúmọ̀ ń bàjẹ́,
A di baba tán, inú ń bí wọn
Ẹni tá ò lè mú Ọlọ́run làá fún
Aróbíẹkẹ́ di baba tan, inú ń bí wọn
Ọmọ òjíbẹ̀dewò, bí ẹlẹ́rú ń kọjá,
Bí ẹlẹ́rú ń kọjá, ẹ pèé mi, ẹgbẹ̀wá lowó ẹ̀
Ọmọ a da ẹrú, bí ẹní da ẹran
Ọmọ ají-má-jàṣán, ají-máà-jẹran tó léegun
Ọmọ ìjoyè, kóyè wuni íjẹ
Joyè lọ́tùn-ún, ọ joyè lósì,
Ó tún joyè nílédì ọbá.
Ọmọ afi ìlẹ̀kẹ̀ so adìẹ tà,
Ilẹ̀kẹ̀ẹ títà, adìẹ títà
Òwò nisẹ́ẹ babaà mi
Ọmọ ẹlẹ́yìnkùlé àdé-súre
“Ọlọ́run jẹ́ kí n dà bí onílé yìí o”.
Ọmọ jagunjagun, òmẹ̀jẹ̀ bí ẹní mu omi
Ó pa igba láàárọ̀, o pa igba lálẹ́
Ó jagun titi, ó fẹ́ẹ̀ẹ́ gbàgbé ilé
Ó bọ̀wá ń mu ọtí, bí ẹní mu omi,
Ó lẹ́ni ojú ọ̀run ń kán,
Kó wá bá òun dábàá ìpórógan.